Home Music Video oba ti ki ye majemu lyrics

oba ti ki ye majemu lyrics

0

1. Oba ti ki ye Majemu,
F’ ore ofe fun wa,
Majemu ti a ba Oda,
Ki awa ko le mu se.

EGBE/CHORUS:-
Nitori iku Messaiah,)2ce
Jowo ko sanu fun wa.)

2. Oba Mimo Oba Ogo,
‘Wo l’ awa nfi iyin fun,
Kerubu ati Serafu,
S’ ope odun titun yi.

3. Alaileso jek’ o s’ eso
Ninu odun t’ awa yi,
Alaigbagbo je ko gbagbo,
Ki gbogbo wa di yiye.

4. Oba Mimo Jehova nla,
Gb’ ope Ajodun wa yi,
Seri ibukun Re sori
Omode at’ agba wa.

5. Pese f’ awon alairise,
Pese omo fun agan,
Fi ilera fun alaisan,
K’ omo Re mase rahun.

6. F’ agbara Re f’ Egbe Serafu
Lati sin O de opin,
Mase je k’ ise wa laiye
Ja s’ asan niwaju Re.

AMIN!


Join our WHATSAPP WHATSAPP CHANNEL or TELEGRAM CHANNEL for instant updates

Leave A Reply

Please enter your comment!
Please enter your name here